O. Daf 98:1-9
O. Daf 98:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀. Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi. O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa. Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn. Ẹ ma fi duru kọrin si Oluwa, ati duru pẹlu ohùn orin-mimọ́. Pẹlu ipè ati ohùn fere, ẹ ho iho ayọ̀ niwaju Oluwa, Ọba. Jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀; aiye, ati awọn ti mbẹ ninu rẹ̀. Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ̀. Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.
O. Daf 98:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu; agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun. OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀, ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli; gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA; ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn. Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA, àní, hapu ati ohùn orin dídùn. Ẹ fun fèrè ati ìwo kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba. Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́; kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀ níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.
O. Daf 98:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ kọrin tuntun sí OLúWA, nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un OLúWA ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀ o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè. Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLúWA, gbogbo ayé, ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn Ẹ fi dùùrù kọrin sí OLúWA, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́, Pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú OLúWA ọba. Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀; Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú OLúWA Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.