O. Daf 91:9-13
O. Daf 91:9-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe ãbo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ. Buburu kan kì yio ṣubu lu ọ, bẹ̃li arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ. Nitori ti yio fi aṣẹ fun awọn angeli rẹ̀ nitori rẹ, lati pa ọ mọ́ li ọ̀na rẹ gbogbo. Nwọn o gbé ọ soke li ọwọ́ wọn, ki iwọ ki o má ba fi ẹṣẹ rẹ gbun okuta. Iwọ o kọja lori kiniun ati pamọlẹ: ẹgbọrọ kiniun ati ejò-nla ni iwọ o fi ẹsẹ tẹ̀-mọlẹ.
O. Daf 91:9-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ, o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ, ibi kankan kò ní dé bá ọ, bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ, pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè, kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta. O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀; ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
O. Daf 91:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìwọ fi OLúWA ṣe ààbò rẹ, ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ. Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ; Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta. Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀; ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.