O. Daf 9:1-6
O. Daf 9:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o fi gbogbo aiya mi yìn Oluwa: emi o fi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ hàn. Emi o yọ̀, emi o si ṣe inu-didùn ninu rẹ, emi o si kọrin iyìn si orukọ rẹ, iwọ Ọga-ogo julọ. Nigbati awọn ọta mi ba pẹhinda, nwọn o ṣubu, nwọn o si ṣegbe ni iwaju rẹ. Nitori iwọ li o ti mu idajọ mi ati idi ọ̀ran mi duro; iwọ li o joko lori itẹ́, ti o nṣe idajọ ododo. Iwọ ba awọn orilẹ-ède wi, iwọ pa awọn enia buburu run, iwọ pa orukọ wọn rẹ́ lai ati lailai. Niti ọta, iparun wọn pari tan lailai: iwọ li o si ti run ilu wọnni; iranti wọn si ti ṣegbe pẹlu wọn.
O. Daf 9:1-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ; n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ. N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ; n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà, wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ. Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre; ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo. O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí, o pa àwọn eniyan burúkú run, o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae. O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro, o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé.
O. Daf 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ó yìn ọ́, OLúWA, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo. Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ; Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà; Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ. Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú; ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo. Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run; Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé. Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá, Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu; àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.