O. Daf 88:5-8
O. Daf 88:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ. Iwọ ti fi mi le ibi isalẹ ti o jìn julọ, ninu okunkun, ninu ọgbun. Ibinu rẹ lẹ̀ mọ mi lara kikan, iwọ si ti fi riru omi rẹ gbogbo ba mi ja. Iwọ ti mu awọn ojulumọ mi jina si mi; iwọ si sọ mi di irira si wọn; a se mi mọ́, emi kò le jade.
O. Daf 88:5-8 Yoruba Bible (YCE)
N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú, mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì, bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́, nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ. O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ, ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun. Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi, ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀. O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀; mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn: mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde
O. Daf 88:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú, ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́, ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú. Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn, ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn. Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi; ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi. Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn. A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde