O. Daf 78:70-72
O. Daf 78:70-72 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si yàn Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá: Lati má tọ̀ awọn agutan lẹhin, ti o tobi fun oyun, o mu u lati ma bọ́ Jakobu, enia rẹ̀, ati Israeli, ilẹ-ini rẹ̀. Bẹ̃li o bọ́ wọn gẹgẹ bi ìwa-titọ inu rẹ̀; o si fi ọgbọ́n ọwọ rẹ̀ ṣe amọna wọn.
Pín
Kà O. Daf 78O. Daf 78:70-72 Yoruba Bible (YCE)
Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀; ó sì mú un láti inú agbo ẹran. Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntan tí ó lọ́mọ lẹ́yìn, kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀. Ó tọ́jú wọn pẹlu òdodo, ó sì tọ́ wọn pẹlu ìmọ̀.
Pín
Kà O. Daf 78O. Daf 78:70-72 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ ó mú láti inú àwọn agbo ẹran; Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu àti Israẹli ogún un rẹ̀. Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn; pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.
Pín
Kà O. Daf 78