O. Daf 75:7-10
O. Daf 75:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke. Nitoripe li ọwọ Oluwa li ago kan wà, ọti-waini na si pọ́n: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rẹ̀; ṣugbọn gèdẹgẹdẹ rẹ̀, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu. Ṣugbọn emi o ma sọ titi lai, emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun Jakobu. Gbogbo iwo awọn enia buburu li emi o ke kuro; ṣugbọn iwo awọn olododo li emi o gbé soke.
O. Daf 75:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú: á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga. Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA, Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀, ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú, yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀; gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún, wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae, n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu. Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò; ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo.
O. Daf 75:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́; Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga. Ní ọwọ́ OLúWA ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá. Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu. Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.