O. Daf 75:1-10
O. Daf 75:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, iwọ li awa fi ọpẹ fun, iwọ li awa fi ọpẹ fun nitori orukọ rẹ sunmọ itosi, iṣẹ iyanu rẹ fi hàn. Nigbati akokò mi ba de, emi o fi otitọ ṣe idajọ. Aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀ warìri: emi li o rù ọwọ̀n rẹ̀. Emi wi fun awọn agberaga pe, Ẹ máṣe gbéraga mọ́: ati fun awọn enia buburu pe, Ẹ máṣe gbé iwo nì soke. Ẹ máṣe gbé iwo nyin ga: ẹ máṣe fi ọrùn lile sọ̀rọ. Nitori ti igbega kò ti ìla-õrùn wá, tabi ni ìwọ-õrùn, bẹ̃ni kì iṣe lati gusu wá. Ṣugbọn Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke. Nitoripe li ọwọ Oluwa li ago kan wà, ọti-waini na si pọ́n: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rẹ̀; ṣugbọn gèdẹgẹdẹ rẹ̀, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu. Ṣugbọn emi o ma sọ titi lai, emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun Jakobu. Gbogbo iwo awọn enia buburu li emi o ke kuro; ṣugbọn iwo awọn olododo li emi o gbé soke.
O. Daf 75:1-10 Yoruba Bible (YCE)
A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́. À ń kéde orúkọ rẹ, a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe. OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó, n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú. Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀; èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú. Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’; èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’ Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ, ẹ má sì gbéraga.” Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn, tabi láti ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá. Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú: á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga. Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA, Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀, ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú, yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀; gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún, wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae, n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu. Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò; ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo.
O. Daf 75:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí; àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ. Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀; Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo. Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì, Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin. Èmí wí fún àwọn agbéraga pé Ẹ má ṣe gbéraga mọ́; àti sí ènìyàn búburú; Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè. Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run; ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.” Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá tàbí ní ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́; Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga. Ní ọwọ́ OLúWA ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá. Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu. Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.