O. Daf 73:13-17
O. Daf 73:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitõtọ li asan ni mo wẹ̀ aiya mi mọ́, ti mo si wẹ̀ ọwọ mi li ailẹ̀ṣẹ. Nitoripe ni gbogbo ọjọ li a nyọ mi lẹnu, a si nnà mi li orowurọ. Bi emi ba pe, emi o fọ̀ bayi: kiyesi i, emi o ṣẹ̀ si iran awọn ọmọ rẹ. Nigbati mo rò lati mọ̀ eyi, o ṣoro li oju mi. Titi mo fi lọ sinu ibi-mimọ́ Ọlọrun; nigbana ni mo mọ̀ igbẹhin wọn.
O. Daf 73:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́, tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu; láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,” n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi, mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ, ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.
O. Daf 73:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀. Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀. Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” Èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi. Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.