O. Daf 71:15-21
O. Daf 71:15-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀. Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan. Ọlọrun, iwọ ti kọ́ mi lati igba ewe mi wá: ati di isisiyi li emi ti nsọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ. Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin. Ọlọrun ododo rẹ ga jọjọ pẹlu, ẹniti o ti nṣe nkan nla: Ọlọrun, tali o dabi iwọ! Iwọ ti o fi iṣẹ nla ati kikan hàn mi, ni yio si tun mi ji, yio si tun mu mi sọ si òke lati ọgbun ilẹ wá. Iwọ o sọ ọlá mi di pupọ̀, iwọ o si tù mi ninu niha gbogbo.
O. Daf 71:15-21 Yoruba Bible (YCE)
N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ, n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru, nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn. N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun, n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan. Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi, títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ, Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi, Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀, títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ, àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀. Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run, ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá, Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ? O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá, ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò; óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú. O óo fi kún ọlá mi, o óo sì tún tù mí ninu.
O. Daf 71:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀. Èmi ó wá láti wá kéde agbára, OLúWA Olódùmarè; èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan. Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ. Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn. Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run, ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá. Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run? Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀. Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.