O. Daf 7:6-11
O. Daf 7:6-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dide Oluwa, ni ibinu rẹ! gbé ara rẹ soke nitori ikannu awọn ọta mi: ki iwọ ki o si jí fun mi si idajọ ti iwọ ti pa li aṣẹ. Bẹ̃ni ijọ awọn enia yio yi ọ ká kiri; njẹ nitori wọn iwọ pada si òke. Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia: Oluwa ṣe idajọ mi, gẹgẹ bi ododo mi, ati gẹgẹ bi ìwatitọ inu mi. Jẹ ki ìwa-buburu awọn enia buburu ki o de opin: ṣugbọn mu olotitọ duro: nitoriti Ọlọrun olododo li o ndan aiya ati inu wò. Abo mi mbẹ lọdọ Ọlọrun ti o nṣe igbala olotitọ li aiya. Ọlọrun li onidajọ ododo, Ọlọrun si nbinu si enia buburu lojojumọ
O. Daf 7:6-11 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, fi ibinu dìde! Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn; jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀. Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká, kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá. OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé; dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi. Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan, fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú, kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀. Ọlọrun ni aláàbò mi, òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là. Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun, a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.
O. Daf 7:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dìde, OLúWA, nínú ìbínú rẹ; dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi. Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo. Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká. Jọba lórí wọn láti òkè wá; Jẹ́ kí OLúWA ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ. Ọlọ́run Olódodo, Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn, tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́. Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà. Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.