O. Daf 69:22-36
O. Daf 69:22-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jẹ ki tabili wọn ki o di ikẹkun niwaju wọn: fun awọn ti o wà li alafia, ki o si di okùn didẹ. Jẹ ki oju wọn ki o ṣú, ki nwọn ki o má riran, ki o si ma mu ẹgbẹ́ wọn gbọn nigbagbogbo. Dà irunu rẹ si wọn lori, si jẹ ki ikannu ibinu rẹ ki o le wọn ba. Jẹ ki ibujoko wọn ki o di ahoro; ki ẹnikẹni ki o máṣe gbe inu agọ wọn. Nitori ti nwọn nṣe inunibini si ẹniti iwọ ti lù; nwọn si nsọ̀rọ ibinujẹ ti awọn ti iwọ ti ṣá li ọgbẹ. Fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ wọn: ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o wá sinu ododo rẹ. Nù wọn kuro ninu iwe awọn alãye, ki a má si kọwe wọn pẹlu awọn olododo. Ṣugbọn talaka ati ẹni-ikãnu li emi, Ọlọrun jẹ ki igbala rẹ ki o gbé mi leke. Emi o fi orin yìn orukọ Ọlọrun, emi o si fi ọpẹ gbé orukọ rẹ̀ ga. Eyi pẹlu ni yio wù Oluwa jù ọda-malu tabi akọ-malu lọ ti o ni iwo ati bàta ẹsẹ. Awọn onirẹlẹ yio ri eyi, inu wọn o si dùn: ọkàn ẹnyin ti nwá Ọlọrun yio si wà lãye. Nitoriti Oluwa gbohùn awọn talaka, kò si fi oju pa awọn ara tubu rẹ̀ rẹ́. Jẹ ki ọrun on aiye ki o yìn i, okun ati ohun gbogbo ti nrakò ninu wọn. Nitoriti Ọlọrun yio gbà Sioni là, yio si kọ́ ilu Juda wọnni: ki nwọn ki o le ma gbe ibẹ, ki nwọn ki o le ma ni i ni ilẹ-ini. Iru-ọmọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ni yio ma jogun rẹ̀: awọn ti o si fẹ orukọ rẹ̀ ni yio ma gbe inu rẹ̀.
O. Daf 69:22-36 Yoruba Bible (YCE)
Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún ara wọn di ẹ̀bìtì fún wọn; kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté. Jẹ́ kí ojú wọn ṣú, kí wọn má lè ríran; kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì. Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí, kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ. Kí ibùdó wọn ó di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn. Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì; ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn; má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ. Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè; kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo. Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora; Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè! Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun; n óo fi ọpẹ́ gbé e ga. Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ, àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i, inú wọn yóo dùn; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí. Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní, kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn. Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín, òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn. Nítorí Ọlọrun yóo gba Sioni là; yóo sì tún àwọn ìlú Juda kọ́; àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa gbé inú rẹ̀, yóo sì di tiwọn. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo jogún rẹ̀; àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ yóo sì máa gbé inú rẹ̀.
O. Daf 69:22-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ fún àwọn tó wà ní àlàáfíà. Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran, kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé. Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn; kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀. Kí ibùjókòó wọn di ahoro; kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù, àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn; Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ. Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo. Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí, Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè. Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga. Eléyìí tẹ́ OLúWA lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀. Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀: ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè! OLúWA, gbọ́ ti aláìní, kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀. Kí ọ̀run àti ayé yìn ín, òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀, nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́. Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní; àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀, àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.