O. Daf 63:1-2 - Compare All Versions
O. Daf 63:1-2 YBCV (Bibeli Mimọ)
ỌLỌRUN, iwọ li Ọlọrun mi; ni kutukutu li emi o ma ṣafẹri rẹ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi, ẹran-ara mi fà si ọ ni ilẹ gbigbẹ, ati ilẹ ti npongbẹ, nibiti omi kò gbe si. Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ.
O. Daf 63:1-2 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ, òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi, ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi. Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ.
O. Daf 63:1-2 YCE (Yoruba Bible)
Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ, ọkàn rẹ ń fà mí; bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹ ṣe máa ń kóǹgbẹ omi. Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ, mo ti rí agbára ati ògo rẹ.