O. Daf 6:1-4
O. Daf 6:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, máṣe ba mi wi ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má ṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ. Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori ailera mi: Oluwa, mu mi lara da; nitori ti ara kan egungun mi. Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to! Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ.
O. Daf 6:1-4 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, má fi ibinu bá mi wí; má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi, OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun. Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá, yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó? OLUWA, pada wá gbà mí, gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
O. Daf 6:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ Ṣàánú fún mi, OLúWA, nítorí èmi ń kú lọ; OLúWA, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira. Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, OLúWA, yóò ti pẹ́ tó? Yípadà, OLúWA, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.