O. Daf 6:1-10
O. Daf 6:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, máṣe ba mi wi ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má ṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ. Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori ailera mi: Oluwa, mu mi lara da; nitori ti ara kan egungun mi. Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to! Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ. Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ? Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi. Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi. Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi. Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi. Oju yio tì gbogbo awọn ọta mi, ara yio sì kan wọn gogo: nwọn o pada, oju yio tì wọn lojíji.
O. Daf 6:1-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, má fi ibinu bá mi wí; má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi, OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun. Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá, yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó? OLUWA, pada wá gbà mí, gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú. Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú? Ìkérora dá mi lágara: ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi; tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì, agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi, nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi. OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi. Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi; ìdààmú ńlá yóo bá wọn, wọn óo sá pada, ojú yóo sì tì wọ́n lójijì.
O. Daf 6:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ Ṣàánú fún mi, OLúWA, nítorí èmi ń kú lọ; OLúWA, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira. Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, OLúWA, yóò ti pẹ́ tó? Yípadà, OLúWA, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í. Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú? Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé. Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi. Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí OLúWA ti gbọ́ igbe mi. OLúWA ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; OLúWA ti gba àdúrà mi. Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.