O. Daf 55:1-8
O. Daf 55:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
FETI si adura mi, Ọlọrun; má si ṣe fi ara rẹ pamọ kuro ninu ẹ̀bẹ mi. Fiye si mi, ki o si da mi lohùn: ara mi kò lelẹ ninu aroye mi, emi si npariwo; Nitori ohùn ọta nì, nitori inilara enia buburu: nitoriti nwọn mu ibi ba mi, ati ni ibinu, nwọn dẹkun fun mi. Aiya dùn mi gidigidi ninu mi: ipaiya ikú si ṣubu lù mi. Ibẹ̀ru ati ìwárìrì wá si ara mi, ati ibẹ̀ru ikú bò mi mọlẹ. Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi. Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju. Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na.
O. Daf 55:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun, má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀. Fetí sí mi, kí o sì dá mi lóhùn; ìṣòro ti borí mi. Ìhàlẹ̀ ọ̀tá bà mí ninu jẹ́, nítorí ìnilára àwọn eniyan burúkú; wọ́n kó ìyọnu bá mi, wọ́n ń bínú mi, inú wọn sì dùn láti máa bá mi ṣọ̀tá. Ọkàn mi wà ninu ìrora, ìpayà ikú ti dé bá mi. Ẹ̀rù ati ìwárìrì dà bò mí, ìpayà sì bò mí mọ́lẹ̀. Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi. Áà! Ǹ bá lọ jìnnà réré, kí n lọ máa gbé inú ijù; ǹ bá yára lọ wá ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ líle ati ìjì.”
O. Daf 55:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run, Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́: Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn. Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo. Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni, nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú; nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi, wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn. Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú; ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi. Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi; ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀. Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi. Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré, kí ń sì dúró sí aginjù; Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò, jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”