O. Daf 53:2-3 - Compare All Versions
O. Daf 53:2-3 YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun bojuwo ilẹ lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun. Gbogbo wọn li o si pada sẹhin, nwọn si di elẽri patapata: kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan.
O. Daf 53:2-3 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn, láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run. Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
O. Daf 53:2-3 YCE (Yoruba Bible)
Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá, ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé, àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ni ó ti yapa; tí wọn sì ti bàjẹ́, kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo.