O. Daf 53:1-3
O. Daf 53:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ nwọn si nṣe irira ẹ̀ṣẹ: kò si ẹniti o nṣe rere. Ọlọrun bojuwo ilẹ lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun. Gbogbo wọn li o si pada sẹhin, nwọn si di elẽri patapata: kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan.
O. Daf 53:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Kò sí Ọlọrun.” Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá, ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé, àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ni ó ti yapa; tí wọn sì ti bàjẹ́, kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo.
O. Daf 53:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé: “Ọlọ́run kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú; kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere. Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn, láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run. Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.