O. Daf 51:13-19
O. Daf 51:13-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li emi o ma kọ́ awọn olurekọja li ọ̀na rẹ: awọn ẹlẹṣẹ yio si ma yipada si ọ. Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọn mi yio si ma kọrin ododo rẹ kikan. Oluwa, iwọ ṣi mi li ète; ẹnu mi yio si ma fi iyìn rẹ han: Nitori iwọ kò fẹ ẹbọ, ti emi iba ru u: inu rẹ kò dùn si ọrẹ-ẹbọ sisun. Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora aiya, Ọlọrun, on ni iwọ kì yio gàn. Ṣe rere ni didùn inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalemu. Nigbana ni inu rẹ yio dùn si ẹbọ ododo; pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọ̀tọtọ ọrẹ-ẹbọ sisun: nigbana ni nwọn o fi akọ-malu rubọ lori pẹpẹ rẹ.
O. Daf 51:13-19 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ. Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun, ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi, n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ. OLUWA, là mí ní ohùn, n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ. Bí ó bá jẹ́ pé o fẹ́ ẹbọ ni, ǹ bá mú wá fún ọ; ṣugbọn o ò tilẹ̀ fẹ́ ẹbọ sísun. Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn. Jẹ́ kí ó dára fún Sioni ninu ìdùnnú rẹ; tún odi Jerusalẹmu mọ. Nígbà náà ni inú rẹ yóo dùn sí ẹbọ tí ó tọ́, ẹbọ sísun, ati ẹbọ tí a sun lódidi; nígbà náà ni a óo fi akọ mààlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ.
O. Daf 51:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ. Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi, ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan. OLúWA, ṣí mi ní ètè mi gbogbo, àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ. Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá; Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun. Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà. Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni, ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ. Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo, pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun, nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.