O. Daf 50:1-15
O. Daf 50:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN Olodumare, ani Oluwa li o ti sọ̀rọ, o si pè aiye lati ìla-õrun wá titi o fi de ìwọ rẹ̀. Lati Sioni wá, pipé ẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ. Ọlọrun wa mbọ̀, kì yio si dakẹ; iná yio ma jó niwaju rẹ̀, ẹfufu lile yio si ma ja yi i ka kiri. Yio si kọ si awọn ọrun lati òke wá, ati si aiye, ki o le ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀. Kó awọn enia mimọ́ mi jọ pọ̀ si ọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi da majẹmu. Awọn ọrun yio si sọ̀rọ ododo rẹ̀: nitori Ọlọrun tikararẹ̀ li onidajọ. Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si sọ̀rọ; Israeli, emi o si jẹri si ọ: emi li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ. Emi kì yio ba ọ wi nitori ẹbọ rẹ, ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ wà niwaju mi nigbagbogbo. Emi kì yio mu akọ-malu lati ile rẹ jade, tabi obukọ ninu agbo-ẹran rẹ: Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke. Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi. Bi ebi npa mi, emi kì yio sọ fun ọ: nitori pe aiye ni ti emi, ati ẹkún inu rẹ̀. Emi o ha jẹ ẹran malu, tabi emi a ma mu ẹ̀jẹ ewurẹ bi? Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo. Ki o si kepè mi ni ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo.
O. Daf 50:1-15 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, Ọlọrun Alágbára ti sọ̀rọ̀: ó ké sí gbogbo ayé láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ọlọrun yọ bí ọjọ́ láti Sioni, ìlú tó dára, tó lẹ́wà. Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́: iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀; ìjì líle sì ń jà yí i ká. Ó ké sí ọ̀run lókè; ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀. Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi, àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!” Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ pé Ọlọrun ni onídàájọ́. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀, Israẹli, n óo takò yín. Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín. N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú; nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi. N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín, tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín. Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó, tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀, tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá. “Bí ebi bá tilẹ̀ pa mí, ẹ̀yin kọ́ ni n óo sọ fún, nítorí èmi ni mo ni gbogbo ayé ati àwọn nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀. Ṣé èmi a máa jẹ ẹran akọ mààlúù? Àbí mà máa mu ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́? Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun, kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo. Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro; n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.”
O. Daf 50:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, Ọlọ́run alágbára sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀. Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà, Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́, iná yóò máa jó níwájú rẹ̀, àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká. Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé, kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀. “Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.” Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀, Nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ: èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ. Èmi kí yóò bá ọ wí nítorí àwọn ìrúbọ rẹ, tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi ní ìgbà gbogbo. Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un, tàbí kí o mú òbúkọ láti inú agbo ẹran rẹ̀ Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ, nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo tí ó wa ní inú rẹ̀. Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ? “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run, kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo. Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”