O. Daf 5:1-6
O. Daf 5:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
FI eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi aroye mi. Fi eti si ohùn ẹkún mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitoripe ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si. Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ, Oluwa, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke. Nitori ti iwọ kì iṣe Ọlọrun ti iṣe inu-didùn si ìwa buburu: bẹ̃ni ibi kò le ba ọ gbe. Awọn agberaga kì yio le duro niwaju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. Iwọ o pa awọn ti nṣe eke run; Oluwa yio korira awọn ẹni-ẹ̀jẹ ati ẹni-ẹ̀tan.
O. Daf 5:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA; kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi. Fetí sí igbe mi, Ọba mi ati Ọlọrun mi, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀, ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ; èmi óo sì máa ṣọ́nà. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú; àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé. Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ; o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi. O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run; OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn.
O. Daf 5:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, OLúWA, kíyèsi àròyé mi. Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí. Ní òwúrọ̀, OLúWA, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé. Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú rẹ̀. Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi; ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni OLúWA yóò kórìíra.