O. Daf 5:1-3
O. Daf 5:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
FI eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi aroye mi. Fi eti si ohùn ẹkún mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitoripe ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si. Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ, Oluwa, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke.
Pín
Kà O. Daf 5O. Daf 5:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA; kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi. Fetí sí igbe mi, Ọba mi ati Ọlọrun mi, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀, ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ; èmi óo sì máa ṣọ́nà.
Pín
Kà O. Daf 5O. Daf 5:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, OLúWA, kíyèsi àròyé mi. Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí. Ní òwúrọ̀, OLúWA, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
Pín
Kà O. Daf 5