O. Daf 49:1-9
O. Daf 49:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸGBỌ́ eyi, gbogbo enia; ẹ fi eti si i, gbogbo ẹnyin araiye: Ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn ẹni-ọlá, awọn ọlọrọ̀ ati awọn talaka pẹlu. Ẹnu mi yio sọ̀rọ ọgbọ́n, ati iṣaro aiya mi yio jẹ oye. Emi o dẹ eti mi silẹ si owe: emi o ṣi ọ̀rọ ìkọkọ mi silẹ loju okùn dùru. Ẽṣe ti emi o fi bẹ̀ru li ọjọ ibi, nigbati ẹ̀ṣẹ awọn ajinilẹsẹ mi yi mi ka. Awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ wọn, ti nwọn si nṣe ileri li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ wọn; Kò si ẹnikan, bi o ti wù ki o ṣe, ti o le rà arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò le san owo-irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀. Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni, o si dẹkun lailai: Nipe ki o fi mã wà lailai, ki o má ṣe ri isa-okú.
O. Daf 49:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè! Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé, ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá, àtolówó ati talaka! Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n; àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye. N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe; n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀. Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu, nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká, àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ? Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada, tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun; nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ. Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀, tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae, kí ó má fojú ba ikú.
O. Daf 49:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé. Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú! Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe, èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù. Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé? Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká, Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn. Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run. Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀, Ní ti kí ó máa wà títí ayé láìrí isà òkú.