O. Daf 49:1-20

O. Daf 49:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸGBỌ́ eyi, gbogbo enia; ẹ fi eti si i, gbogbo ẹnyin araiye: Ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn ẹni-ọlá, awọn ọlọrọ̀ ati awọn talaka pẹlu. Ẹnu mi yio sọ̀rọ ọgbọ́n, ati iṣaro aiya mi yio jẹ oye. Emi o dẹ eti mi silẹ si owe: emi o ṣi ọ̀rọ ìkọkọ mi silẹ loju okùn dùru. Ẽṣe ti emi o fi bẹ̀ru li ọjọ ibi, nigbati ẹ̀ṣẹ awọn ajinilẹsẹ mi yi mi ka. Awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ wọn, ti nwọn si nṣe ileri li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ wọn; Kò si ẹnikan, bi o ti wù ki o ṣe, ti o le rà arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò le san owo-irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀. Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni, o si dẹkun lailai: Nipe ki o fi mã wà lailai, ki o má ṣe ri isa-okú. Nitori o nri pe awọn ọlọgbọ́n nkú, bẹ̃li aṣiwere ati ẹranko enia nṣegbe, nwọn si nfi ọrọ̀ wọn silẹ fun ẹlomiran. Ìro inu wọn ni, ki ile wọn ki o pẹ titi lai, ati ibujoko wọn lati irandiran; nwọn sọ ilẹ wọn ní orukọ ara wọn. Ṣugbọn enia ti o wà ninu ọlá kò duro pẹ: o dabi ẹranko ti o ṣegbé. Ipa ọ̀na wọn yi ni igbẹkẹle wọn: ọ̀rọ wọn si tọ́ li oju awọn ọmọ wọn. Bi agutan li a ntẹ wọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rẹ̀ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn. Ṣugbọn Ọlọrun ni yio rà ọkàn mi lọwọ isa-okú: nitoripe on o gbà mi. Iwọ máṣe bẹ̀ru, nitori ẹnikan di ọlọrọ̀, nitori iyìn ile rẹ̀ npọ̀ si i. Nitoripe, igbati o ba kú, kì yio kó ohun kan lọ: ogo rẹ̀ kì yio sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ. Nigbati o wà lãye bi o tilẹ nsure fun ọkàn ara rẹ̀: ti awọn enia nyìn ọ, nigbati iwọ nṣe rere fun ara rẹ. Ọkàn yio lọ si ọdọ iran awọn baba rẹ̀; nwọn kì yio ri imọlẹ lailai. Ọkunrin ti o wà ninu ọlá, ti kò moye, o dabi ẹranko ti o ṣegbe.

O. Daf 49:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè! Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé, ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá, àtolówó ati talaka! Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n; àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye. N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe; n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀. Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu, nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká, àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ? Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada, tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun; nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ. Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀, tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae, kí ó má fojú ba ikú. Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n, òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run; wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae, ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé, wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn. Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé, bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú. Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí, òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn. Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn, ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn; ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà. Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́, Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀, ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn. Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikú nítorí pé yóo gbà mí. Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó, tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú, kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ; dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè, ó rò pé Ọlọrun bukun òun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyan nígbà tí nǹkan bá ń dára fún un, yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú, kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́. Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé; bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku.

O. Daf 49:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé. Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú! Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe, èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù. Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé? Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká, Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn. Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run. Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀, Ní ti kí ó máa wà títí ayé láìrí isà òkú. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé, ibùgbé wọn láti ìrandíran, wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé. Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela. Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀; Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú, yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀. Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú, ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀. Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere. Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀ àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé. Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.