O. Daf 47:1-9
O. Daf 47:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸNYIN enia, gbogbo ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ̀ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun. Nitori Oluwa Ọga-ogo li ẹ̀ru; on li ọba nla lori ilẹ-aiye gbogbo. On ni yio ṣẹ́ awọn enia labẹ wa, ati awọn orilẹ-ède li atẹlẹsẹ wa. On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ. Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè. Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyìn si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn. Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn. Ọlọrun jọba awọn keferi: Ọlọrun joko lori itẹ ìwa-mimọ́ rẹ̀. Awọn alade awọn enia kó ara wọn jọ, ani awọn enia Ọlọrun Abrahamu: nitori asà aiye ti Ọlọrun ni: on li a gbe leke jọjọ.
O. Daf 47:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè; ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun. Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo, Ọba ńlá lórí gbogbo ayé. Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa, ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa. Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa, èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn. A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀, a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè. Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn; Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn! Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé; Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn! Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀. Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu. Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé; òun ni ọlọ́lá jùlọ!
O. Daf 47:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀. Báwo ni OLúWA Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó ọba ńlá lórí gbogbo ayé. Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa. Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀, OLúWA ti òun ti ariwo ìpè. Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn. Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn! Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé, ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu! Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí; Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀. Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni, òun ni ó ga jùlọ.