O. Daf 46:1-7
O. Daf 46:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN li àbo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju. Nitorina li awa kì yio bẹ̀ru, bi a tilẹ ṣi aiye ni idi, ti a si ṣi awọn oke nla nipò lọ si inu okun: Bi omi rẹ̀ tilẹ nho ti o si nru, bi awọn òke nla tilẹ nmì nipa ọwọ bibì rẹ̀. Odò nla kan wà, ṣiṣan eyiti yio mu inu ilu Ọlọrun dùn, ibi mimọ́ agọ wọnni ti Ọga-ogo. Ọlọrun mbẹ li arin rẹ̀; a kì yio ṣi i ni idi: Ọlọrun yio ràn a lọwọ ni kutukutu owurọ. Awọn keferi nbinu, awọn ilẹ ọba ṣidi: o fọhun rẹ̀, aiye yọ́. Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.
O. Daf 46:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa, olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú. Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí, bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun; bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru, tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtì nítorí agbára ríru rẹ̀. Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn, ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo. Ọlọrun wà láàrin rẹ̀, kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò; Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu. Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru, àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n; OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́. OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.
O. Daf 46:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú. Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí, tí òkè sì ṣubú sínú Òkun. Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela. Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé. Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú, ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀. Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.