O. Daf 41:7-10
O. Daf 41:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo awọn ti o korira mi jumọ nsọ̀rọ kẹlẹ́ si mi: emi ni nwọn ngbìmọ ibi si. Pe, ohun buburu li o dì mọ ọ ṣinṣin: ati ibiti o dubulẹ si, kì yio dide mọ. Nitõtọ ọrẹ-iyọrẹ ara mi, ẹniti mo gbẹkẹle, ẹniti njẹ ninu onjẹ mi, o gbe gigisẹ rẹ̀ si mi. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ṣãnu fun mi, ki o si gbé mi dide, ki emi ki o le san a fun wọn.
O. Daf 41:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi jọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi; ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi. Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀; kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.” Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé, tí ó ń jẹun nílé mi, ó ti kẹ̀yìn sí mí. Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi; gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un.
O. Daf 41:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi; èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí, wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́.” Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi. Ṣùgbọ́n ìwọ OLúWA, ṣàánú fún mi; gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.