O. Daf 41:1-4
O. Daf 41:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
IBUKÚN ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, Oluwa yio gbà a ni ìgbà ipọnju. Oluwa yio pa a mọ́, yio si mu u wà lãye; a o si bukún fun u lori ilẹ: iwọ kì yio si fi i le ifẹ awọn ọta rẹ̀ lọwọ. Oluwa yio gbà a ni iyanju lori ẹní àrun: iwọ o tẹ ẹní rẹ̀ gbogbo ni ibulẹ arun rẹ̀. Emi wipe, Oluwa ṣãnu fun mi: mu ọkàn mi lara da; nitori ti mo ti ṣẹ̀ si ọ.
O. Daf 41:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní: OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú. OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí. Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà; OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, OLUWA yóo fún un lókun; ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn. Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn; mo ti ṣẹ̀ ọ́.”
O. Daf 41:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní: OLúWA yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. OLúWA yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́: yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀ kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLúWA yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀ yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀. Ní ti èmi, mo wí pé “OLúWA, ṣàánú fún mi; wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.