O. Daf 41:1-13

O. Daf 41:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní: OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú. OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí. Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà; OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, OLUWA yóo fún un lókun; ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn. Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn; mo ti ṣẹ̀ ọ́.” Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé, “Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?” Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò, ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìí ni yóo máa sọ; bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà. Nígbà tí ó bá jáde, yóo máa rò mí kiri. Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi jọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi; ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi. Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀; kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.” Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé, tí ó ń jẹun nílé mi, ó ti kẹ̀yìn sí mí. Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi; gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un. Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi, nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi. O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi, o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae. Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Amin! Amin!

O. Daf 41:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní: OLúWA yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. OLúWA yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́: yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀ kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLúWA yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀ yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀. Ní ti èmi, mo wí pé “OLúWA, ṣàánú fún mi; wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”. Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?” Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀; nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀. Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi; èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí, wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́.” Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi. Ṣùgbọ́n ìwọ OLúWA, ṣàánú fún mi; gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn. Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi, nítorí ọ̀tá mi kò borí mi. Bí ó ṣe tèmi ni ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé. Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli láé àti láéláé. Àmín àti Àmín.