O. Daf 40:11-17
O. Daf 40:11-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo. Nitoripe ainiye ibi li o yika kiri: ẹ̀ṣẹ mi dì mọ mi, bẹ̃li emi kò le gbé oju wò oke, nwọn jù irun ori mi lọ: nitorina aiya mi npá mi. Ki o wù ọ, Oluwa, lati gbà mi: Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ, Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si damu pọ̀, awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run; ki a lé wọn pada sẹhin, ki a si dojuti awọn ti nfẹ mi ni ibi. Ki nwọn ki o di ofo fun ère itiju wọn, awọn ti nwi fun mi pe, A! a! Ki gbogbo awọn ti nwá ọ, ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn sipa tirẹ: ki gbogbo awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Gbigbega li Oluwa. Ṣugbọn talaka ati alaini li emi; Oluwa si nṣe iranti mi; iwọ ni iranlọwọ mi ati olugbala mi: máṣe pẹ titi, Ọlọrun mi.
O. Daf 40:11-17 Yoruba Bible (YCE)
Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA, sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́. Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká, ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí, tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran. Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, ọkàn mi ti dàrú. OLUWA, dákun gbà mi; yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí mi, kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata, jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn, kí wọ́n sì tẹ́. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n, kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú, àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ; kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!” Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí; ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi, má pẹ́, Ọlọrun mi.
O. Daf 40:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; OLúWA jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé. Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́; wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà. Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ OLúWA, láti gbà mí là; OLúWA, yára láti ràn mí lọ́wọ́. Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì kí wọn kí ó sì dààmú àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun: jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n, àwọn tí ń wá ìpalára mi. Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!” ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ kí ó máa yọ̀ kí inú wọn sì máa dùn sí ọ; kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ kí o máa wí nígbà gbogbo pé, “Gbígbéga ni OLúWA!” Bí ó ṣe ti èmi ni, tálákà àti aláìní ni èmi, ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti ìgbàlà mi; Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́, ìwọ Ọlọ́run mi.