O. Daf 37:27-40

O. Daf 37:27-40 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere; kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae. Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́; kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀. Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae, ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run. Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà; wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere, a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́. Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀; ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀. Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo, ó ń wá ọ̀nà ati pa á. OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́, tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀, yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i. Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni, tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni. Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá, mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́; mo wá a, ṣugbọn n kò rí i. Ṣe akiyesi ẹni pípé; sì wo olódodo dáradára, nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára. Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata, a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá; òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro. OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n; a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, a sì máa gbà wọ́n là, nítorí pé òun ni wọ́n sá di.

O. Daf 37:27-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé. Nítorí pé OLúWA fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò. Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà, yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé. Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́. Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn; àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀. Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo, Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á. OLúWA kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi, nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Dúró de OLúWA, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́. Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri. Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà, ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá, ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́; bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri. Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin; nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀; ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò. Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA; òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú OLúWA yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n; yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.