O. Daf 37:1-3
O. Daf 37:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù. Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ.
Pín
Kà O. Daf 37O. Daf 37:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi; nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko; wọn óo sì rọ bí ewé. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́.
Pín
Kà O. Daf 37O. Daf 37:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko, wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù. Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
Pín
Kà O. Daf 37