O. Daf 35:9-10
O. Daf 35:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀. Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun?
Pín
Kà O. Daf 35O. Daf 35:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA, n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀. N óo fi gbogbo ara wí pé, “OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ? Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbára lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára tí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.”
Pín
Kà O. Daf 35O. Daf 35:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú OLúWA, àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀. Gbogbo egungun mi yóò wí pé, “Ta ni ó dàbí ì ìwọ OLúWA? O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ, tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
Pín
Kà O. Daf 35