O. Daf 31:1-13

O. Daf 31:1-13 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA, ìwọ ni mo sá di, má jẹ́ kí ojú tì mí lae; gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́. Dẹ etí sí mi, yára gbà mí. Jẹ́ àpáta ààbò fún mi; àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là. Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi; nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí. Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí, nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi. Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́, o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́. Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn, ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé. N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi, o sì mọ ìṣòro mi. O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́, o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì; àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi. Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi; ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji. Ìpọ́njú ti gba agbára mi; gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi, àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò. Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi, àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi. Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú; mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò. Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi, tí wọ́n sì ń pète ati pa mí; wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.

O. Daf 31:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nínú rẹ̀, OLúWA ni mo ti rí ààbò; Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ. Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi. Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, OLúWA, Ọlọ́run òtítọ́. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé OLúWA. Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú. Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá. Ṣàánú fún mi, ìwọ OLúWA, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú. Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù. Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi; àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi. Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú; Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́. Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká; tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi láti gba ẹ̀mí mi.