O. Daf 27:1-9

O. Daf 27:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? OLúWA ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí? Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran-ara mi, àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ OLúWA, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé OLúWA ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà OLúWA, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí OLúWA. Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! OLúWA, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn; “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.” Ojú rẹ, OLúWA, ni èmí ń wá. Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì; ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi, Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí, háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.

O. Daf 27:1-9

O. Daf 27:1-9 YBCVO. Daf 27:1-9 YBCV