O. Daf 27:1-3
O. Daf 27:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bẹ̀ru? Oluwa li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi? Nigbati awọn enia buburu, ani awọn ọta mi ati awọn abinuku mi sunmọ mi lati jẹ ẹran ara mi, nwọn kọsẹ, nwọn si ṣubu. Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le.
O. Daf 27:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi; ta ni n óo bẹ̀rù? OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóo bà mí? Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi, tí wọ́n fẹ́ pa mí, àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi, wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú. Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí àyà mi kò ní já. Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi, sibẹ, ọkàn mi kò ní mì.
O. Daf 27:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? OLúWA ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí? Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran-ara mi, àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.