O. Daf 21:1-13
O. Daf 21:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌBA yio ma yọ̀ li agbara rẹ, Oluwa; ati ni igbala rẹ, yio ti yọ̀ pọ̀ to! Iwọ ti fi ifẹ ọkàn rẹ̀ fun u, iwọ kò si dù u ni ibère ẹnu rẹ̀. Nitori iwọ ti fi ibukún ore kò o li ọ̀na, iwọ fi ade kiki wura de e li ori. O tọrọ ẹmi lọwọ rẹ, iwọ si fi fun u, ani ọjọ gigùn lai ati lailai. Ogo rẹ̀ pọ̀ ni igbala rẹ: iyìn ati ọlánla ni iwọ fi si i lara. Nitori iwọ ti ṣe e li ẹni-ibukún fun jùlọ titi aiye: iwọ si fi oju rẹ mu u yọ̀ gidigidi. Nitori ti ọba gbẹkẹle Oluwa, ati nipa ãnu Ọga-ogo kì yio ṣipò pada. Ọwọ rẹ yio wá gbogbo awọn ọta rẹ ri: ọwọ ọtún rẹ ni yio wá awọn ti o korira rẹ ri. Iwọ o ṣe wọn bi ileru onina ni igba ibinu rẹ: Oluwa yio gbé wọn mì ni ibinu rẹ̀, iná na yio si jó wọn pa. Eso wọn ni iwọ o run kuro ni ilẹ, ati irú-ọmọ wọn kuro ninu awọn ọmọ enia. Nitori ti nwọn nrò ibi si ọ: nwọn ngbìro ete ìwa-ibi, ti nwọn kì yio le ṣe. Nitorina ni iwọ o ṣe mu wọn pẹhinda, nigbati iwọ ba fi ọfà rẹ kàn ọsán si oju wọn. Ki iwọ ki ó ma leke, Oluwa, li agbara rẹ; bẹ̃li awa o ma kọrin, ti awa o si ma yìn agbara rẹ.
O. Daf 21:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA; inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́! O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́, o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú. O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀; o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí. Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un, àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé. Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́; o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀. Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae; o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀. Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; a kò ní ṣí i ní ipò pada, nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀. Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ. O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn. OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀; iná yóo sì jó wọn ní àjórun. O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé, o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan. Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ, tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é. Nítorí pé o óo lé wọn sá; nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn. A gbé ọ ga, nítorí agbára rẹ, OLUWA! A óo máa kọrin, a óo sì máa yin agbára rẹ.
O. Daf 21:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Háà! OLúWA, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ, àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó! Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela. Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí. Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un, àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé. Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un; ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ. Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un: ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀. Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OLúWA; nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà kì yóò sípò padà. Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí. Nígbà tí ìwọ bá yọ ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru. OLúWA yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run. Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀, àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn. Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí. Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà. Gbígbéga ni ọ́ OLúWA, nínú agbára rẹ; a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.