O. Daf 20:1-9
O. Daf 20:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
KI Oluwa ki o gbohùn rẹ li ọjọ ipọnju; orukọ Ọlọrun Jakobu ki o dàbobo ọ. Ki o rán iranlọwọ si ọ lati ibi-mimọ́ wá, ki o si tì ọ lẹhin lati Sioni wá. Ki o ranti ẹbọ-ọrẹ rẹ gbogbo, ki o si gbà ẹbọ sisun rẹ. Ki o fi fun ọ gẹgẹ bi ti inu rẹ, ki o si mu gbogbo ìmọ rẹ ṣẹ. Awa o ma kọrin ayọ̀ igbala rẹ, ati li orukọ Ọlọrun wa li awa o fi ọpágun wa de ilẹ; ki Oluwa ki o mu gbogbo ibère rẹ ṣẹ. Nigbayi ni mo to mọ̀ pe Oluwa gbà Ẹni-ororo rẹ̀ là; yio gbọ́ ọ lati ọrun mimọ́ rẹ̀ wá nipa agbara igbala ọwọ ọ̀tun rẹ̀. Awọn ẹlomiran gbẹkẹle kẹkẹ́, awọn ẹlomiran le ẹṣin; ṣugbọn awa o ranti orukọ Oluwa Ọlọrun wa. Nwọn wolẹ, nwọn si ṣubu: ṣugbọn awa dide awa si duro ṣinṣin. Gbani, Oluwa, ki Ọba ki o gbọ nigbati awa ba nkigbe pe e.
O. Daf 20:1-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́. Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá, yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ, yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ. Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ, yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ. Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun, ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀; OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ. Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́; OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá yóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin, ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa. Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú, ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin. Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA; kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́.
O. Daf 20:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí OLúWA kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́. Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ. Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé: OLúWA pa ẹni ààmì òróró rẹ̀ mọ́. Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin, ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLúWA Ọlọ́run wa. Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú, ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin. OLúWA, fi ìṣẹ́gun fún ọba! Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!