O. Daf 2:7-12
O. Daf 2:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ. Bère lọwọ mi, emi o si fi awọn orilẹ-ède fun ọ ni ini rẹ, ati iha opin ilẹ li ọrọ̀-ilẹ rẹ. Ọpá irin ni iwọ o fi fọ́ wọn; iwọ o si rún wọn womuwomu, bi ohun èlo amọ̀. Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n, ẹnyin ọba: ki a si kọ́ nyin, ẹnyin onidajọ aiye. Ẹ fi ìbẹru sìn Oluwa, ẹ si ma yọ̀ ti ẹnyin ti iwarìri. Fi ẹnu kò Ọmọ na lẹnu, ki o máṣe binu, ẹnyin a si ṣegbe li ọ̀na na, bi inu rẹ̀ ba ru diẹ kiun. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.
O. Daf 2:7-12 Yoruba Bible (YCE)
N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba; Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ. Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ. Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn, o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.” Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA, ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì. Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú, kí ó má baà pa yín run lójijì; nítorí a máa yára bínú. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.
O. Daf 2:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò sì kéde ìpinnu OLúWA: Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí, èmi ti di baba rẹ. Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ. Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.” Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n; ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé. Ẹ sin OLúWA pẹ̀lú ìbẹ̀rù ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì. Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú, kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín, nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.