O. Daf 2:1-4
O. Daf 2:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẼṢE ti awọn orilẹ-ède fi nbinu fùfu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan? Awọn ọba aiye kẹsẹ jọ, ati awọn ijoye ngbimọ pọ̀ si Oluwa ati si Ẹni-ororo rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a fa ìde wọn já, ki a si mu okùn wọn kuro li ọdọ wa. Ẹniti o joko li ọrun yio rẹrin: Oluwa yio yọ ṣùti si wọn.
O. Daf 2:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán? Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀. Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.” Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín; OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.
O. Daf 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán? Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí OLúWA àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.” Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.