O. Daf 18:1-3
O. Daf 18:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi. OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà. Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
O. Daf 18:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi. Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi. Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.
O. Daf 18:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi. OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà. Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
O. Daf 18:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fẹ́ ọ, OLúWA, agbára mi. OLúWA ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi. Mo ké pe OLúWA, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.