O. Daf 145:8-13
O. Daf 145:8-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olore-ọfẹ li Oluwa, o kún fun ãnu; o lọra lati binu, o si li ãnu pupọ̀. Oluwa ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọ́nu rẹ̀ si mbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo. Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yio ma yìn ọ; awọn enia mimọ́ rẹ yio si ma fi ibukún fun ọ. Nwọn o ma sọ̀rọ ogo ijọba rẹ, nwọn o si ma sọ̀rọ agbara rẹ: Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn ọmọ enia, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo, Ijọba rẹ ijọba aiye-raiye ni, ati ijọba rẹ lati iran-diran gbogbo.
O. Daf 145:8-13 Yoruba Bible (YCE)
Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni; kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá. OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́. Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ, wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ, láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ, ati ẹwà ògo ìjọba rẹ. Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ, yóo sì máa wà láti ìran dé ìran.
O. Daf 145:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olóore-ọ̀fẹ́ ni OLúWA àti aláàánú ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀. OLúWA dára sí ẹni gbogbo; ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá. Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni yóò máa yìn ọ́ OLúWA; àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ. Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ, Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀ àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo. Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni, àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.