O. Daf 145:17-21
O. Daf 145:17-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olododo li Oluwa li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati alãnu ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo. Oluwa wà leti ọdọ gbogbo awọn ti nkepè e, leti ọdọ gbogbo ẹniti nkepè e li otitọ. Yio mu ifẹ awọn ti mbẹ̀ru rẹ̀ ṣẹ: yio gbọ́ igbe wọn pẹlu, yio si gbà wọn. Oluwa da gbogbo awọn ti o fẹ ẹ si: ṣugbọn gbogbo enia buburu ni yio parun. Ẹnu mi yio ma sọ̀rọ iyìn Oluwa: ki gbogbo enia ki o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́ lai ati lailai.
O. Daf 145:17-21 Yoruba Bible (YCE)
Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀, aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é, àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn. Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn; ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n. OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí, ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run. Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA; kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae.
O. Daf 145:17-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá. OLúWA wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́. Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ; ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n. OLúWA dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni búburú ní yóò parun. Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn OLúWA. Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.