O. Daf 145:1-6
O. Daf 145:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o gbé ọ ga, Ọlọrun mi, ọba mi; emi o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ lai ati lailai. Li ojojumọ li emi o ma fi ibukún fun ọ; emi o si ma yìn orukọ rẹ lai ati lailai. Titobi li Oluwa, o si ni iyìn pupọ̀-pupọ̀; awamaridi si ni titobi rẹ̀. Iran kan yio ma yìn iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọ̀rọ iṣẹ agbara rẹ. Emi o sọ̀rọ iyìn ọla-nla rẹ ti o logo, ati ti iṣẹ iyanu rẹ. Enia o si ma sọ̀rọ agbara iṣẹ rẹ ti o li ẹ̀ru; emi o si ma ròhin titobi rẹ.
O. Daf 145:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi, n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́, tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ; àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀. Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ, tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ. Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu rẹ. Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu, èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ.
O. Daf 145:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi; Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́ èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé. Títóbi ni OLúWA. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀: kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀. Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn; wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ. Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.