O. Daf 140:1-13
O. Daf 140:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA gbà mi lọwọ ọkunrin buburu nì, yọ mi lọwọ ọkunrin ìka nì; Ẹniti nrò ìwa-buburu ni inu wọn; nigbagbogbo ni nwọn nrú ìja soke si mi. Nwọn ti pọ́n ahọn wọn bi ejo; oro pãmọlẹ mbẹ li abẹ ète wọn. Oluwa, pa mi mọ́ kuro lọwọ enia buburu; yọ mi kuro lọwọ ọkunrin ìka nì; ẹniti o ti pinnu rẹ̀ lati bì ìrin mi ṣubu. Awọn agberaga dẹ pakute silẹ fun mi, ati okùn; nwọn ti nà àwọn lẹba ọ̀na; nwọn ti kẹkùn silẹ fun mi. Emi wi fun Oluwa pe, iwọ li Ọlọrun mi: Oluwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi. Ọlọrun Oluwa, agbara igbala mi, iwọ li o bò ori mi mọlẹ li ọjọ ìja. Oluwa, máṣe fi ifẹ enia buburu fun u: máṣe kún ọgbọ́n buburu rẹ̀ lọwọ: ki nwọn ki o má ba gbé ara wọn ga. Bi o ṣe ti ori awọn ti o yi mi ká kiri ni, jẹ ki ìka ète ara wọn ki o bò wọn mọlẹ. A o da ẹyin iná si wọn lara: on o wọ́ wọn lọ sinu iná, sinu ọgbun omi jijin, ki nwọn ki o má le dide mọ́. Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye: ibi ni yio ma dọdẹ ọkunrin ìka nì lati bì i ṣubu. Emi mọ̀ pe, Oluwa yio mu ọ̀ran olupọnju duro, ati are awọn talaka. Nitõtọ awọn olododo yio ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ: awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ma gbe iwaju rẹ.
O. Daf 140:1-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi; dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá; àwọn tí ó ń pète ibi lọ́kàn wọn, tí wọ́n sì ń dá ogun sílẹ̀ nígbàkúùgbà, Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn, ó mú bí ahọ́n ejò; oró paramọ́lẹ̀ sì ń bẹ ninu eyín wọn. OLUWA, ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú; dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá, tí ó ń gbìmọ̀ láti ré mi lẹ́pa. Àwọn agbéraga ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí, wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi; wọ́n sì dẹ okùn sílẹ̀ fún mi lẹ́bàá ọ̀nà. Mo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.” OLUWA, tẹ́tí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA, OLUWA mi, alágbára tíí gbani là, ìwọ ni o dáàbò bò mí ní ọjọ́ ogun. OLUWA, má jẹ́ kí ọwọ́ àwọn eniyan burúkú tẹ ohun tí wọn ń wá; má jẹ́ kí èrò ọkàn wọn ṣẹ. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ibi ẹnu àwọn tí ó yí mi ká dà lé wọn lórí. Jẹ́ kí ẹ̀yinná dà lé wọn lórí; jẹ́ kí wọn já sí kòtò, kí wọn má lè yọ. Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà; jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá. Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò, yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní. Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ; àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ.
O. Daf 140:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì; Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn; nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi. Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn. OLúWA, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú; yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn: wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà; wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi. Èmi wí fún OLúWA pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; OLúWA, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLúWA Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà. OLúWA, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un; Má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́; kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela. Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni, jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀. A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára: Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná, sínú ọ̀gbun omi jíjìn, kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́. Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé; ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú. Èmi mọ̀ pé, OLúWA yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ; àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.