O. Daf 14:1-6
O. Daf 14:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ, nwọn si nṣe iṣẹ irira, kò si ẹniti nṣe rere. Oluwa bojuwò lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun. Gbogbo wọn li o si jumọ yà si apakan, nwọn si di elẽri patapata; kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan. Gbogbo awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ kò ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun, nwọn kò si kepè Oluwa. Nibẹ ni ẹ̀ru bà wọn gidigidi: nitoriti Ọlọrun mbẹ ninu iran olododo. Ẹnyin dojutì ìmọ awọn talaka, ṣugbọn Oluwa li àbo rẹ̀.
O. Daf 14:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá, ó wo àwọn ọmọ eniyan, láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n, tí wọn ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ti ṣìnà, gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni? Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun, àwọn tí kì í ké pe OLUWA. Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi, nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo. Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú, ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀.
O. Daf 14:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Ko sí Ọlọ́run.” Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú; kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere. OLúWA sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run. Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́; kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀? Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun; wọn kò sì ké pe OLúWA? Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù, nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo. Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú, ṣùgbọ́n OLúWA ni ààbò wọn.