O. Daf 139:7-8,11-12
O. Daf 139:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ? Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ.
O. Daf 139:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka. Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ.
O. Daf 139:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀? Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi? Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀! Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀.
ORIN DAFIDI 139:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀, kí ọ̀sán di òru fún mi, òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ; òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn.