O. Daf 139:3-6
O. Daf 139:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ yi ipa ọ̀na mi ká ati ibulẹ mi, gbogbo ọ̀na mi si di mimọ̀ fun ọ. Nitori ti kò si ọ̀rọ kan li ahọn mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ patapata. Iwọ sé mi mọ lẹhin ati niwaju, iwọ si fi ọwọ rẹ le mi. Iru ìmọ yi ṣe ohun iyanu fun mi jù; o ga, emi kò le mọ̀ ọ.
O. Daf 139:3-6 Yoruba Bible (YCE)
O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò; gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀. Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata. O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn; o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi, ó ga jù, ojú mi kò tó o.
O. Daf 139:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, OLúWA, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá. Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.