O. Daf 138:1-8
O. Daf 138:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o ma yìn ọ tinu-tinu mi gbogbo; niwaju awọn oriṣa li emi o ma kọrin iyìn si ọ. Emi o ma gbadura siha tempili mimọ́ rẹ, emi o si ma yìn orukọ rẹ nitori iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ; nitori iwọ gbé ọ̀rọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ. Li ọjọ ti mo kepè, iwọ da mi lohùn, iwọ si fi ipa mu mi lara le li ọkàn mi. Gbogbo awọn ọba aiye yio yìn ọ, Oluwa, nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ. Nitõtọ, nwọn o ma kọrin ni ipa-ọ̀na Oluwa: nitori pe nla li ogo Oluwa. Bi Oluwa tilẹ ga, sibẹ o juba awọn onirẹlẹ; ṣugbọn agberaga li o mọ̀ li òkere rére. Bi emi tilẹ nrìn ninu ipọnju, iwọ ni yio sọ mi di ãye: iwọ o nà ọwọ rẹ si ibinu awọn ọta mi, ọwọ ọtún rẹ yio si gbà mi. Oluwa yio ṣe ohun ti iṣe ti emi li aṣepe: Oluwa, ãnu rẹ duro lailai: máṣe kọ̀ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ.
O. Daf 138:1-8 Yoruba Bible (YCE)
N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA, lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ. Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ, n óo sì máa yin orúkọ rẹ, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ, nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ. Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn, o sì fún mi ní agbára kún agbára. OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́, nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA, nítorí pé ògo OLUWA tóbi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá, ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí, ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè. Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú, sibẹ, o dá mi sí; o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi, o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí. OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi, OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀.
O. Daf 138:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo; níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ. Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ. Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi. Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, OLúWA, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà OLúWA; nítorí pé ńlá ni ògo OLúWA. Bí OLúWA tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré. Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè; ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí. OLúWA yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé; OLúWA, àánú rẹ dúró láéláé; Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.