O. Daf 137:1-6
O. Daf 137:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ẹba odò Babeli, nibẹ li awa gbe joko, awa si sọkun nigbati awa ranti Sioni. Awa fi duru wa kọ́ si ori igi wíllo ti o wà lãrin rẹ̀. Nitoripe nibẹ li awọn ti o kó wa ni igbekun bère orin lọwọ wa; ati awọn ti o ni wa lara bère idaraya wipe; Ẹ kọ orin Sioni kan fun wa. Awa o ti ṣe kọ orin Oluwa ni ilẹ àjeji? Jerusalemu, bi emi ba gbagbe rẹ, jẹ ki ọwọ ọtún mi ki o gbagbe ìlò rẹ̀. Bi emi kò ba ranti rẹ, jẹ ki ahọn mi ki o lẹ̀ mọ èrìgì mi; bi emi kò ba fi Jerusalemu ṣaju olori ayọ̀ mi gbogbo.
O. Daf 137:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún, nígbà tí a ranti Sioni. Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn ti ní kí á kọrin fún àwọn. Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.” Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì? Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ, kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ. Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi, bí n kò bá ranti rẹ, bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.
O. Daf 137:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni. Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò, tí ó wà láàrín rẹ̀. Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé; ẹ kọ orin Sioni kan fún wa. Àwa ó ti ṣe kọ orin OLúWA ní ilẹ̀ àjèjì Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀. Bí èmi kò bá rántí rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi; bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo.