O. Daf 136:1-3
O. Daf 136:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
O. Daf 136:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.